الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني القرآن الكريم للغة اليوربا ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني عام الطبعة 1432هـ .﴿بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ حم﴾
Hā mīm.
﴿تَنْزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ﴾
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
﴿مَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُسَمًّى ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا عَمَّا أُنْذِرُوا مُعْرِضُونَ﴾
A ò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn.
﴿قُلْ أَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ۖ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِنْ قَبْلِ هَٰذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِنْ عِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ﴾
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
﴿وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ يَدْعُو مِنْ دُونِ اللَّهِ مَنْ لَا يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَنْ دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ﴾
Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n.
﴿وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاءً وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ﴾
Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn.
﴿وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ﴾
Nígbà tí wọ́n bá ń ké áwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa sọ ìsọkúsọ sí òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: "Èyí ni idán pọ́nńbélé."
﴿أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَلَا تَمْلِكُونَ لِي مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِ ۖ كَفَىٰ بِهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۖ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ﴾
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Sọ pé: "Tí mo bá hun ún fúnra mi, ẹ ò ní ìkápá kiní kan fún mi ní ọ̀dọ̀ Allāhu (níbi ìyà Rẹ̀). Òun ni Onímọ̀-jùlọ nípa ìsọkúsọ tí ẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀. Ó (sì) tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
﴿قُلْ مَا كُنْتُ بِدْعًا مِنَ الرُّسُلِ وَمَا أَدْرِي مَا يُفْعَلُ بِي وَلَا بِكُمْ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ وَمَا أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُبِينٌ﴾
Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."
﴿قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كَانَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَكَفَرْتُمْ بِهِ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ مِثْلِهِ فَآمَنَ وَاسْتَكْبَرْتُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ﴾
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
﴿وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا لَوْ كَانَ خَيْرًا مَا سَبَقُونَا إِلَيْهِ ۚ وَإِذْ لَمْ يَهْتَدُوا بِهِ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَا إِفْكٌ قَدِيمٌ﴾
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān jẹ́ oore ni, wọn kò níí ṣíwájú wa débẹ̀." Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò ti tẹ̀lé ìmọ̀nà rẹ̀, ni wọ́n ń wí pé: "Irọ́ ijọ́un ni èyí."
﴿وَمِنْ قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ وَهَٰذَا كِتَابٌ مُصَدِّقٌ لِسَانًا عَرَبِيًّا لِيُنْذِرَ الَّذِينَ ظَلَمُوا وَبُشْرَىٰ لِلْمُحْسِنِينَ﴾
Tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn. Al-Ƙur’ān) yìí tún ni Tírà kan t’ó ń jẹ́rìí sí òdodo ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn t’ó ṣàbòsí, (ó sì jẹ́) ìró ìdùnnú fún àwọn olùṣe-rere.
﴿إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ﴾
Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa", lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, kò níí sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
﴿أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ﴾
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
﴿وَوَصَّيْنَا الْإِنْسَانَ بِوَالِدَيْهِ إِحْسَانًا ۖ حَمَلَتْهُ أُمُّهُ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا ۖ وَحَمْلُهُ وَفِصَالُهُ ثَلَاثُونَ شَهْرًا ۚ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَبَلَغَ أَرْبَعِينَ سَنَةً قَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِي أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ الَّتِي أَنْعَمْتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَالِدَيَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَالِحًا تَرْضَاهُ وَأَصْلِحْ لِي فِي ذُرِّيَّتِي ۖ إِنِّي تُبْتُ إِلَيْكَ وَإِنِّي مِنَ الْمُسْلِمِينَ﴾
A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù.
(Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí."
﴿أُولَٰئِكَ الَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنْهُمْ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا وَنَتَجَاوَزُ عَنْ سَيِّئَاتِهِمْ فِي أَصْحَابِ الْجَنَّةِ ۖ وَعْدَ الصِّدْقِ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ﴾
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
﴿وَالَّذِي قَالَ لِوَالِدَيْهِ أُفٍّ لَكُمَا أَتَعِدَانِنِي أَنْ أُخْرَجَ وَقَدْ خَلَتِ الْقُرُونُ مِنْ قَبْلِي وَهُمَا يَسْتَغِيثَانِ اللَّهَ وَيْلَكَ آمِنْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ فَيَقُولُ مَا هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ﴾
Ẹni tí ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì pé: "Ṣíọ̀ ẹ̀yin méjèèjì! Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣèlérí fún mi pé Wọn yóò mú mi jáde (láàyè láti inú sàréè), ṣebí àwọn ìran kan ti ré kọjá lọ ṣíwájú mi (tí Wọn kò tí ì mú wọn jáde láti inú sàréè wọn)." Àwọn (òbí rẹ̀) méjèèjì sì ń tọrọ ìgbàlà ní ọ̀dọ̀ Allāhu (fún ọmọ yìí. Wọ́n sì sọ pé): "Ègbé ni fún ọ! (O jẹ́) gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo." (Ọ̀mọ̀ náà sì) wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́."
﴿أُولَٰئِكَ الَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمْ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا خَاسِرِينَ﴾
Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
﴿وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِمَّا عَمِلُوا ۖ وَلِيُوَفِّيَهُمْ أَعْمَالَهُمْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ﴾
Àwọn ipò yóò wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Àti pé (èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Àwa kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
﴿وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَذْهَبْتُمْ طَيِّبَاتِكُمْ فِي حَيَاتِكُمُ الدُّنْيَا وَاسْتَمْتَعْتُمْ بِهَا فَالْيَوْمَ تُجْزَوْنَ عَذَابَ الْهُونِ بِمَا كُنْتُمْ تَسْتَكْبِرُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَبِمَا كُنْتُمْ تَفْسُقُونَ﴾
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n máa sọ fún wọn pé:) "Ẹ ti lo ìgbádùn yín tán nínú ìṣẹ̀mí ayé? Ẹ sì ti jẹ ìgbádùn ayé? Nítorí náà, ní òní, wọ́n máa san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí pé ẹ̀ ń ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣèbàjẹ́."
﴿۞ وَاذْكُرْ أَخَا عَادٍ إِذْ أَنْذَرَ قَوْمَهُ بِالْأَحْقَافِ وَقَدْ خَلَتِ النُّذُرُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ﴾
Ṣèrántí arákùnrin (ìjọ) ‘Ād. Nígbà tí ó ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ t’ó ń gbé nínú yanrìn tí atẹ́gùn kójọ bí òkè. Àwọn olùkìlọ̀ sì ti ré kọjá ṣíwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀. (Ó sì sọ pé:) "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá kan fun yín."
﴿قَالُوا أَجِئْتَنَا لِتَأْفِكَنَا عَنْ آلِهَتِنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ﴾
Wọ́n wí pé: "Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo."
﴿قَالَ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِنْدَ اللَّهِ وَأُبَلِّغُكُمْ مَا أُرْسِلْتُ بِهِ وَلَٰكِنِّي أَرَاكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ﴾
Ó sọ pé: "Ìmọ̀ (nípa rẹ̀) wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo. Èmi yó sì jẹ́ iṣẹ́ tí Wọ́n fi rán mi dé òpin fun yín, ṣùgbọ́n èmi ń ri ẹ̀yin ní ìjọ aláìmọ̀kan."
﴿فَلَمَّا رَأَوْهُ عَارِضًا مُسْتَقْبِلَ أَوْدِيَتِهِمْ قَالُوا هَٰذَا عَارِضٌ مُمْطِرُنَا ۚ بَلْ هُوَ مَا اسْتَعْجَلْتُمْ بِهِ ۖ رِيحٌ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٌ﴾
Nígbà tí wọ́n rí ìyà náà ní ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, t’ó ń wọ́ bọ̀ wá sínú àwọn kòtò ìlú wọn, wọ́n wí pé: "Èyí ni ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tí ó máa rọ̀jò fún wa." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ni. Atẹ́gùn tí ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà nínú rẹ̀ ni.
﴿تُدَمِّرُ كُلَّ شَيْءٍ بِأَمْرِ رَبِّهَا فَأَصْبَحُوا لَا يُرَىٰ إِلَّا مَسَاكِنُهُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْقَوْمَ الْمُجْرِمِينَ﴾
Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
﴿وَلَقَدْ مَكَّنَّاهُمْ فِيمَا إِنْ مَكَّنَّاكُمْ فِيهِ وَجَعَلْنَا لَهُمْ سَمْعًا وَأَبْصَارًا وَأَفْئِدَةً فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ سَمْعُهُمْ وَلَا أَبْصَارُهُمْ وَلَا أَفْئِدَتُهُمْ مِنْ شَيْءٍ إِذْ كَانُوا يَجْحَدُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ﴾
A kúkú fún wọn ní ipò tí A ò fún ẹ̀yin. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po.
﴿وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا مَا حَوْلَكُمْ مِنَ الْقُرَىٰ وَصَرَّفْنَا الْآيَاتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ﴾
Àwa kúkú ti pa rẹ́ nínú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká yín. Àwa sì ti ṣàlàyé àwọn āyah náà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
﴿فَلَوْلَا نَصَرَهُمُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ قُرْبَانًا آلِهَةً ۖ بَلْ ضَلُّوا عَنْهُمْ ۚ وَذَٰلِكَ إِفْكُهُمْ وَمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ﴾
Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
﴿وَإِذْ صَرَفْنَا إِلَيْكَ نَفَرًا مِنَ الْجِنِّ يَسْتَمِعُونَ الْقُرْآنَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوا أَنْصِتُوا ۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوْا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ مُنْذِرِينَ﴾
(Rántí) nígbà tí A darí ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú sí ọ, tí wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ al-Ƙur’ān. Nígbà tí wọ́n dé síbẹ̀, wọ́n sọ pé: "Ẹ dákẹ́ (fún al-Ƙur’ān)." Nígbà tí wọ́n sì parí (kíké rẹ̀ tán), wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ (fún wọn).
﴿قَالُوا يَا قَوْمَنَا إِنَّا سَمِعْنَا كِتَابًا أُنْزِلَ مِنْ بَعْدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٍ مُسْتَقِيمٍ﴾
Wọ́n sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ wa, dájúdájú àwa gbọ́ (nípa) Tírà kan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn (Ànábì) Mūsā, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ni sí ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà tààrà.
﴿يَا قَوْمَنَا أَجِيبُوا دَاعِيَ اللَّهِ وَآمِنُوا بِهِ يَغْفِرْ لَكُمْ مِنْ ذُنُوبِكُمْ وَيُجِرْكُمْ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ﴾
Ẹ̀yin ìjọ wa, ẹ jẹ́ ìpè olùpèpè Allāhu. Kí ẹ sì gbà á gbọ́ ní òdodo. (Allāhu) yó sì forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa yọ yín kúrò nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
﴿وَمَنْ لَا يُجِبْ دَاعِيَ اللَّهِ فَلَيْسَ بِمُعْجِزٍ فِي الْأَرْضِ وَلَيْسَ لَهُ مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءُ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ﴾
Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì jẹ́pè olùpèpè Allāhu, kò lè mórí bọ́ mọ́ (Allāhu) lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."
﴿أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَمْ يَعْيَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَنْ يُحْيِيَ الْمَوْتَىٰ ۚ بَلَىٰ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ﴾
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí kò sì káàárẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá wọn, (ṣé kò) ní agbára láti sọ àwọn òkú di alààyè ni? Rárá, (Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
﴿وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۖ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ﴾
(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sórí Iná, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé:) "Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?" Wọn yóò wí pé: "Rárá, (òdodo ni) Olúwa wa." (Allāhu máa) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́."
﴿فَاصْبِرْ كَمَا صَبَرَ أُولُو الْعَزْمِ مِنَ الرُّسُلِ وَلَا تَسْتَعْجِلْ لَهُمْ ۚ كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَ مَا يُوعَدُونَ لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا سَاعَةً مِنْ نَهَارٍ ۚ بَلَاغٌ ۚ فَهَلْ يُهْلَكُ إِلَّا الْقَوْمُ الْفَاسِقُونَ﴾
Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Al-Ƙur’ān yìí sì ni ìjíṣẹ́ dópin. Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
الترجمات والتفاسير لهذه السورة:
- سورة الأحقاف : الترجمة الأمهرية አማርኛ - الأمهرية
- سورة الأحقاف : اللغة العربية - المختصر في تفسير القرآن الكريم العربية - العربية
- سورة الأحقاف : اللغة العربية - التفسير الميسر العربية - العربية
- سورة الأحقاف : اللغة العربية - معاني الكلمات العربية - العربية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأسامية অসমীয়া - الأسامية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأذرية Azərbaycanca / آذربايجان - الأذرية
- سورة الأحقاف : الترجمة البنغالية বাংলা - البنغالية
- سورة الأحقاف : الترجمة البوسنية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Bosanski - البوسنية
- سورة الأحقاف : الترجمة البوسنية - كوركت Bosanski - البوسنية
- سورة الأحقاف : الترجمة البوسنية - ميهانوفيتش Bosanski - البوسنية
- سورة الأحقاف : الترجمة الألمانية - بوبنهايم Deutsch - الألمانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الألمانية - أبو رضا Deutsch - الألمانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإنجليزية - صحيح انترناشونال English - الإنجليزية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإنجليزية - هلالي-خان English - الإنجليزية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإسبانية Español - الإسبانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإسبانية - المنتدى الإسلامي Español - الإسبانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإسبانية (أمريكا اللاتينية) - المنتدى الإسلامي Español - الإسبانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفارسية للمختصر في تفسير القرآن الكريم فارسی - الفارسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفارسية - دار الإسلام فارسی - الفارسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفارسية - حسين تاجي فارسی - الفارسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفرنسية - المنتدى الإسلامي Français - الفرنسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفرنسية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Français - الفرنسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الغوجراتية ગુજરાતી - الغوجراتية
- سورة الأحقاف : الترجمة الهوساوية هَوُسَ - الهوساوية
- سورة الأحقاف : الترجمة الهندية हिन्दी - الهندية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإندونيسية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Bahasa Indonesia - الأندونيسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإندونيسية - شركة سابق Bahasa Indonesia - الأندونيسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإندونيسية - المجمع Bahasa Indonesia - الأندونيسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإندونيسية - وزارة الشؤون الإسلامية Bahasa Indonesia - الأندونيسية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإيطالية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Italiano - الإيطالية
- سورة الأحقاف : الترجمة الإيطالية Italiano - الإيطالية
- سورة الأحقاف : الترجمة اليابانية 日本語 - اليابانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الكازاخية - مجمع الملك فهد Қазақша - الكازاخية
- سورة الأحقاف : الترجمة الكازاخية - جمعية خليفة ألطاي Қазақша - الكازاخية
- سورة الأحقاف : الترجمة الخميرية ភាសាខ្មែរ - الخميرية
- سورة الأحقاف : الترجمة الكورية 한국어 - الكورية
- سورة الأحقاف : الترجمة الكردية Kurdî / كوردی - الكردية
- سورة الأحقاف : الترجمة المليبارية മലയാളം - المليبارية
- سورة الأحقاف : الترجمة الماراتية मराठी - الماراتية
- سورة الأحقاف : الترجمة النيبالية नेपाली - النيبالية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأورومية Oromoo - الأورومية
- سورة الأحقاف : الترجمة البشتوية پښتو - البشتوية
- سورة الأحقاف : الترجمة البرتغالية Português - البرتغالية
- سورة الأحقاف : الترجمة السنهالية සිංහල - السنهالية
- سورة الأحقاف : الترجمة الصومالية Soomaaliga - الصومالية
- سورة الأحقاف : الترجمة الألبانية Shqip - الألبانية
- سورة الأحقاف : الترجمة التاميلية தமிழ் - التاميلية
- سورة الأحقاف : الترجمة التلجوية తెలుగు - التلجوية
- سورة الأحقاف : الترجمة الطاجيكية - عارفي Тоҷикӣ - الطاجيكية
- سورة الأحقاف : الترجمة الطاجيكية Тоҷикӣ - الطاجيكية
- سورة الأحقاف : الترجمة التايلاندية ไทย / Phasa Thai - التايلاندية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفلبينية (تجالوج) للمختصر في تفسير القرآن الكريم Tagalog - الفلبينية (تجالوج)
- سورة الأحقاف : الترجمة الفلبينية (تجالوج) Tagalog - الفلبينية (تجالوج)
- سورة الأحقاف : الترجمة التركية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Türkçe - التركية
- سورة الأحقاف : الترجمة التركية - مركز رواد الترجمة Türkçe - التركية
- سورة الأحقاف : الترجمة التركية - شعبان بريتش Türkçe - التركية
- سورة الأحقاف : الترجمة التركية - مجمع الملك فهد Türkçe - التركية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأويغورية Uyƣurqə / ئۇيغۇرچە - الأويغورية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأوكرانية Українська - الأوكرانية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأردية اردو - الأردية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأوزبكية - علاء الدين منصور Ўзбек - الأوزبكية
- سورة الأحقاف : الترجمة الأوزبكية - محمد صادق Ўзбек - الأوزبكية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفيتنامية للمختصر في تفسير القرآن الكريم Vèneto - الفيتنامية
- سورة الأحقاف : الترجمة الفيتنامية Vèneto - الفيتنامية
- سورة الأحقاف : الترجمة اليورباوية Yorùbá - اليوروبا
- سورة الأحقاف : الترجمة الصينية 中文 - الصينية